2 Kings 23:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wó gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe panṣaga fún ìsìn Aṣera ń gbé létí ilé OLUWA lulẹ̀, níbi tí àwọn obinrin ti máa ń hun aṣọ fún ìsìn Aṣera.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wó ile awọn ti nhù ìwa panṣaga, ti mbẹ leti ile Oluwa, nibiti awọn obinrin wun aṣọ-agọ fun ere-oriṣa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé OLÚWA àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà (òriṣà).