2 Kings 23:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Juda ni ó mú wá sí Jerusalẹmu, ó sì ba gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n ti ń rúbọ jẹ́. Ó wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní ẹnubodè, tí Joṣua, baálẹ̀ ìlú kọ́, tí ó wà ní apá òsì, bí eniyan bá ti fẹ́ wọ ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó gbogbo awọn alufa jade kuro ni ilu Juda wọnni, o si sọ ibi giga wọnni di ẽri nibiti awọn alufa ti sun turari, lati Geba titi de Beer-ṣeba, o si wó ibi giga ẹnu-ibodè wọnni ti mbẹ ni atiwọ̀ ẹnu-ibodè Joṣua bãlẹ ilu, ti mbẹ lapa osi ẹni, ni atiwọ̀ ẹnu-ibode ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.