2 Kings 24:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọdún kẹjọ tí ọba Babiloni jọba ni Jehoiakini ọba Juda jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Babiloni, ó sì jọ̀wọ́ ìyá rẹ̀, àwọn iranṣẹ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pẹlu, ọba Babiloni bá kó wọn ní ìgbèkùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoiakini ọba Juda si jade tọ̀ ọba Babeli lọ, on, ati iya rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn iwẹfa rẹ̀: ọba Babeli si mu u li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóíákímù ọba Júdà àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un. Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Bábílónì ó mú Jéhóíákínì ẹlẹ́wọ̀n.