2 Kings 24:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó gbogbo iṣura ile Oluwa lọ kuro nibẹ, ati iṣura ile ọba, o si ké gbogbo ohun-èlo wura wẹwẹ ti Solomoni ọba Israeli ti ṣe ni tempili Oluwa, bi Oluwa ti sọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ Nebukadinéṣárì kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé OLÚWA àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì