2 Kings 24:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó kó gbogbo Jerusalẹmu ní ìgbèkùn; gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn akọni, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaarun (10,000), kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan ní ìlú náà, àfi àwọn talaka.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó gbogbo Jerusalemu lọ, ati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo awọn alagbara akọni enia, ani ẹgbãrun igbèkun, ati gbogbo awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹ̀dẹ: kò kù ẹnikan, bikòṣe iru awọn ti o jẹ talakà ninu awọn enia ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ti kọ́ fún OLÚWA, Ó kó wọn lọ sí ìgbékùn gbogbo Jérúsálẹ́mù: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárún ún, àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.