2 Kings 24:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọla, ẹ̃dẹgbãrin, ati awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹdẹ ẹgbẹrun, gbogbo awọn ti o li agbara ti o si yẹ fun ogun, ani awọn li ọba Babeli kó ni igbèkun lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Bábílónì àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) alágbára ọkùnrin, alágbára tí ó yẹ fún ogun, àti àwọn ẹgbẹ̀rùn (1000) oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ.