2 Kings 24:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì rán àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Aráméánì, àwọn ará Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì. Ó rán wọn láti pa Júdà run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ nípaṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.