2 Kings 25:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa ọdún kẹsan-an ìjọba rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ odi yí i ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣù kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣù, ni Nebukadnessari ọba Babeli de, on, ati gbogbo ogun rẹ̀, si Jerusalemu, o si dotì i; nwọn si mọdi tì i yika kiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó di ọdún kẹsàn án ìjọba Ṣédékíàyà. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadinésárì ọba Bábílónì yan lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn isẹ ìdọ̀tì fi yí gbogbo rẹ̀ ká.