2 Kings 25:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ ni ile Oluwa, ati ijoko wọnni, ati agbada-nla idẹ ti o wà ni ile Oluwa, li awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó idẹ wọn lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Bábílónì fọ́ ọwọ́n idẹ sí túútúú, àti ìjòkòó àti agbada ńlá idẹ tí ó wà nílé OLÚWA wọ́n sì kọ́ idẹ wọn sí Bábílónì.