2 Kings 25:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati inu ilu, o mu iwẹ̀fa kan ti a fi ṣe olori awọn ologun, ati ọkunrin marun ninu awọn ti o wà niwaju ọba, ti a ri ni ilu, ati akọwe olori ogun, ti ntò awọn enia ilẹ na, ati ọgọta ọkunrin ninu awọn enia ilẹ na ti a ri ni ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìjòyè tí ó fi sí ipò olórí àwọn ológun ọkùnrin àti àwọn agbà oní ní ìmọ̀ràn ọba. Ó sì tún mú akọ̀wé tí ó jẹ́ ìjòyè tí ń to àwọn ènìyàn ilé náà àti mẹ́fà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.