2 Kings 25:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn enia ti o kù ni ilẹ Juda, ti Nebukadnessari ọba Babeli fi silẹ, ani, o fi Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, jẹ bãlẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nebukadínésárì ọba Bábílónì ó mú Gédalíàh ọmọ Áhíkámù ọmọ ṣáfánì, láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó ti fa kalẹ̀ lẹ́yìn ní Júdà.