2 Kings 25:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati gbogbo awọn olori ogun, awọn ati awọn ọkunrin wọn, si gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah jẹ bãlẹ, nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ati Johanani ọmọ Karea, ati Seraiah ọmọ Tanhumeti ara Netofati, ati Jaasaniah ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gédálíàh gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gédálíàh ni Mísípà. Ísímáélì ọmọ Nétaníàh, Jóhánánì ọmọ Káréà, Séráíáyà ọmọ Tánhúmétì ará Nétófátì, Jásáníáyà ọmọ ara Mákà, àti àwọn ọkùnrin wọn.