2 Kings 25:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ni gbogbo wọn, àtọmọdé, àtàgbà, ati àwọn olórí ogun bá gbéra, wọ́n kó lọ sí Ijipti, nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea bà wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo enia, ti ewe ti àgba, ati awọn olori ogun, si dide, nwọn si wá si Egipti: nitoriti nwọn bẹ̀ru ara Kaldea.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sá lọ si Éjíbítì nítorí ẹ̀rù àwọn ará Bábílónì.