2 Kings 25:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Jehoiakini ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kejila ọdún náà, Efilimerodaki, ọba Babiloni, gbé ọ̀rọ̀ Jehoiakini yẹ̀wò, ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọdun kẹtadilogoji igbèkun Jehoiakini ọba Juda, li oṣù kejila, li ọjọ kẹtadilọgbọn oṣù, Efil-merodaki ọba Babeli, li ọdun ti o bẹ̀rẹ si ijọba, o gbé ori Jehoiakini ọba Juda soke kuro ninu tubu;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí a lé Jéhóíákínì ọba Júdà kúrò nílú, ní ọdún tí Efili-Méródákì di ọba Bábílónì, ó tú Jéhóíákínì kúrò nínú túbú ní ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣú kéjìlá.