2 Kings 25:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni wọ́n lu odi ìlú náà, ọba ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n lu odi ìlú náà, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin odi mejeeji lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, wọ́n sì gba ọ̀nà tí ó lọ sí Araba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà odi ìlú náà sì fón ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun sá lọ ní òru láti ẹnu ọ̀nà bodè láàrin ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, lára àwọn ará Bábílónì wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sá lọ sí ìkọjá Árábù.