2 Kings 25:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si pa awọn ọmọ Sedekiah li oju rẹ̀, nwọn si fọ Sedekiah li oju, nwọn si fi ẹwọn idẹ dè e, nwọn si mu u lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì pa ọmọ Ṣédékáyà níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Bábílónì.