2 Kings 3:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì sì wí pé, “Ṣé kò sí wòlíì OLÚWA níbí, tí àwa ìbá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì wà níbí. Ó máa ṣábà bu omi sí ọwọ́ Èlíjàh.”