2 Kings 3:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliṣa sọ fún Joramu ọba pé, “Lọ sọ́dọ̀ àwọn wolii baba ati ìyá rẹ. Àbí, kí ló pa èmi ati ìwọ pọ̀?” Joramu dáhùn pé, “Rárá, OLUWA ni ó ti pe àwa ọba mẹtẹẹta yìí jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eliṣa si wi fun ọba Israeli pe, Kini o ṣe mi ṣe ọ? Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃kọ: nitori ti Oluwa ti pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa? Lọ sọ́dọ̀ wòlíì bàbá rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ.” “Rárá,” ọba Ísírẹ́lì dá a lóhùn, “nítorí OLÚWA ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́.”