2 Kings 3:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò ní rí ìjì tabi òjò, sibẹsibẹ àwọn odò gbígbẹ náà yóo kún fún omi, ti yóo fi jẹ́ pé ẹ̀yin ati àwọn mààlúù yín ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóo rí ọpọlọpọ omi mu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni OLÚWA wí: O kò níí rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.