2 Kings 3:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba mẹtẹẹta ń bọ̀ láti gbógun tì wọ́n, wọ́n pe gbogbo àwọn tí wọ́n lè lọ sógun jọ, ati àgbà ati ọmọde, wọ́n sì fi wọ́n sí àwọn ààlà ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati gbogbo ara Moabu gbọ́ pe, awọn ọba gòke wá lati ba wọn jà, nwọn kó gbogbo awọn ti o le hamọra ogun jọ, ati awọn ti o dagba jù wọn lọ, nwọn si duro li eti ilẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyí gbogbo ará Móábù gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà: Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀.