2 Kings 3:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kígbe pé, “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Dájúdájú àwọn ọba mẹtẹẹta wọnyi ti bá ara wọn jà, wọ́n sì ti pa ara wọn, ẹ jẹ́ kí á lọ kó ìkógun ninu ibùdó-ogun wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, Ẹ̀jẹ li eyi: awọn ọba na run: nwọn si ti pa ara wọn; njẹ nisisiyi, Moabu, dide si ikogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsìn yìí sí àwọn ìkógun Móábù!”