2 Kings 3:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n pa àwọn ìlú wọn run, gbogbo ilẹ̀ oko tí ó dára ni wọ́n da òkúta sí títí tí gbogbo wọn fi kún. Wọ́n dí gbogbo orísun omi, wọ́n sì gé gbogbo àwọn igi dáradára. Kiri Heresi tíí ṣe olú-ìlú wọn nìkan ni wọn kò pa run, ṣugbọn àwọn tí wọn ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì ṣẹgun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wó gbogbo ilu, olukulùku si jù okuta tirẹ̀ si gbogbo oko rere, nwọn si kún wọn; nwọn si dí gbogbo kanga omi, nwọn si bẹ́ gbogbo igi rere: ni Kirharaseti ni nwọn fi kiki awọn okuta rẹ̀ silẹ ṣugbọn awọn oni-kànakana yi i ka, nwọn si kọlù u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì wọ gbogbo ìlú náà olúkúlùkù ènìyàn, wọ́n ju òkúta sí gbogbo ohun dáradára orí pápá títí tí ó fi run. Wọ́n sì dá gbogbo orísun omi dúró wọ́n sì gé gbogbo orísun dáradára. Kíríháráṣétì nìkan ni wọ́n fi òkúta rẹ̀ sílẹ̀ ní àyè rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ológun pẹ̀lú kanakáná yíká, wọ́n sì kọlù ìlú náà.