2 Kings 3:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ó fi àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin, tí ó yẹ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa Moabu, ní orí odi ìlú náà. Ibinu ńlá dé bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi í sílẹ̀, wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o mu akọbi ọmọ rẹ̀ ti iba jọba ni ipò rẹ̀, o si fi i rubọ sisun li ori odi. Ibinu nla si wà si Israeli: nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, nwọn si pada si ilẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ó mú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, tí kò bá jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì fi rú ẹbọ sísun ní orí ògiri ìlú. Wọ́n sì bínú lórí Ísírẹ́lì púpọ̀púpọ̀; wọ́n yọ́ kúrò wọ́n sì padà sí ìlú wọn.