2 Kings 3:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ni Joramu, ati ọba Juda ati ọba Edomu bá gbéra láti lọ sójú ogun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ọjọ́ meje, kò sí omi mímu mọ́ fún wọn ati fún àwọn ẹranko tí wọ́n ru ẹrù wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ọba Isírẹ́lì jáde lọ pẹ̀lú ọba Júdà àti ọba Édómù. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn.