2 Kings 4:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun u pe, nisisiyi, sọ fun u pe, Kiyesi i, iwọ ti fi gbogbo itọju yi ṣe aniyàn wa; kini a ba ṣe fun ọ? Iwọ nfẹ́ ki a sọ̀rọ rẹ fun ọba bi? tabi fun olori-ogun? On si dahùn wipe, Emi ngbe lãrin awọn enia mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa. Nísinsìn yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ” “Ṣé alèjẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?”