2 Kings 4:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.” Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi bẹ̀ ọ, sure nisisiyi ki o pade rẹ̀, ki o si wi fun u pe, Alafia ki o wà bi? alafia ki ọkọ rẹ̀ wà bi? alafia ki ọmọde wà bi? On si dahùn wipe, Alafia ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáadáa? Ṣé ọkọ rẹ wà dáadáa? Ṣé ọmọ rẹ wà dáadáa?’ ” Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáadáa.”