2 Kings 4:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de ọdọ enia Ọlọrun li ori òke, o gbá a li ẹsẹ̀ mu: ṣugbọn Gehasi sunmọ ọ lati tì i kurò. Enia Ọlọrun na si wipe, Jọwọ rẹ̀ nitori ọkàn rẹ̀ bajẹ ninu rẹ̀, Oluwa si pa a mọ́ fun mi, kò si sọ fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹṣẹ̀ mú. Géhásì wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú, Kíkorò, ṣùgbọ́n OLÚWA fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.”