2 Kings 4:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Géhásì sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn dídún. Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì padà lọ láti lọ bá Èlíṣà láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”