2 Kings 4:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà padà sí Gílgálì ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì ṣe ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”