2 Kings 4:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan si jade lọ si igbẹ lati fẹ́ ewebẹ̀, o si ri ajara-igbẹ kan, o si ka eso rẹ̀ kún aṣọ rẹ̀, o si rẹ́ ẹ wẹwẹ, o dà wọn sinu ikoko ipẹ̀tẹ na: nitoripe nwọn kò mọ̀ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà ìgbẹ́. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ.