2 Kings 4:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin kan si ti Baali-Ṣaliṣa wá, o si mu àkara akọso-eso, ogun iṣu àkara barle, ati ṣiri ọkà titun ninu àpo rẹ̀ wá fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin kan wá láti Báálì-Ṣálíṣà, ó sì mú ogún ìṣù àkàrà bárílè, àkàrà tí wọ́n dín láti ara àkọ́kọ́ gbó àgbàdo, àti pẹ̀lú síírì ọkà tuntun. “Fún àwọn ènìyàn láti jẹ,” Èlíṣà wí pé