2 Kings 4:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?” Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kinla, ki emi ki o gbé eyi kà iwaju ọgọrun enia? On si tun wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ: nitori bayi li Oluwa wi pe, Nwọn o jẹ, nwọn o si kù silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́ọ̀rún ènìyàn (100 men)?” Ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè. Ṣùgbọ́n Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: ‘Wọn yóò jẹ yóò sì tún sẹ́kù’ ”