2 Kings 4:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si di ọjọ kan, Eliṣa si kọja si Ṣunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wà; on si rọ̀ ọ lati jẹ onjẹ. O si ṣe, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a yà si ibẹ lati jẹ onjẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan Èlíṣà lọ sí Ṣúnémù. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun.