2 Kings 5:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.” Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò ní gba ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Námánì rọ̀ ọ́ láti gbàá, ó kọ̀.