2 Kings 5:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Naamani bá ní, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè láti bu erùpẹ̀ ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ meji lọ sílé nítorí láti òní lọ, iranṣẹ rẹ kì yóo rúbọ sí ọlọrun mìíràn bíkòṣe OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Tí o kò bá ní gba,” Námánì wí pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí èmi, ìránṣẹ́ rẹ fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ẹrùpẹ̀ ìbaka méjì, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rúbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn ṣùgbọ́n OLÚWA.