2 Kings 5:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nígbà tí Gehasi, iranṣẹ Eliṣa, sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Olúwa mi jẹ́ kí Naamani ará Siria yìí lọ láì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi OLUWA búra pé, n óo sáré tẹ̀lé e láti gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Géhásì, ìránṣẹ́ Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ̀ lórí Námánì, ará Árámù, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ńi ọwọ́ rẹ̀.”