2 Kings 5:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Naamani sì rọ̀ ọ́ kí ó gba ìwọ̀n talẹnti meji. Ó di owó náà sinu àpò meji pẹlu aṣọ meji. Ó pàṣẹ fún iranṣẹ meji kí wọ́n bá Gehasi gbé wọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Naamani si wipe, Fi ara balẹ, gbà talenti meji. O si rọ̀ ọ, o si dì talenti fadakà meji sinu apò meji, pẹlu ipàrọ aṣọ meji, o si gbé wọn rù ọmọ-ọdọ rẹ̀ meji; nwọn si rù wọn niwaju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Námánì wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Géhásì láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Géhásì.