2 Kings 5:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ìdí èyí, ẹ̀tẹ̀ Naamani yóo lẹ̀ mọ́ ọ lára ati ìdílé rẹ ati ìrandíran rẹ títí lae.” Gehasi sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Eliṣa ní adẹ́tẹ̀, ó funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ̀tẹ Naamani yio lẹ mọ ọ, ati iru-ọmọ rẹ titi lai. On si jade kuro niwaju rẹ̀, li adẹtẹ̀ ti o funfun bi ojodidì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀tẹ̀ Námánì yóò rọ̀mọ́ ọ àti sí irú ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Géhásì kúrò níwájú Èlíṣà, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.