2 Kings 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Israẹli pẹlu ìwé náà. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí, “Ẹni tí ó mú ìwé yìí wá ni Naamani, iranṣẹ mi, mo rán an wá sọ́dọ̀ rẹ kí o lè wò ó sàn ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu iwe na tọ̀ ọba Israeli wá, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba de ọdọ rẹ, kiyesi i, emi rán Naamani iranṣẹ mi si ọ, ki iwọ ki o le wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Námánì sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”