2 Kings 5:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọba Israẹli ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù rẹ̀ hàn, ó sì wí pé, “Èmi ha í ṣe Ọlọrun tí ó ní agbára ikú ati ìyè bí, tí ọba Siria fi rò wí pé mo lè wo eniyan sàn kúrò ninu ẹ̀tẹ̀? Èyí fi hàn pé ó ń wá ìjà ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati ọba Israeli kà iwe na tan, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Emi ha iṣe Ọlọrun, lati pa ati lati sọ di ãyè, ti eleyi fi ranṣẹ si mi lati ṣe awòtan enia kan kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀? nitorina, ẹ rò o wò, mo bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò o bi on ti nwá mi ni ijà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọba Ísírẹ́lì ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí àyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”