2 Kings 6:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu wọn dáhùn pé, “Kò sí ẹnìkan ninu wa tí ń sọ àṣírí fún ọba Israẹli. Wolii Eliṣa ní ń sọ fún un, títí kan gbogbo ohun tí ẹ bá sọ ní kọ̀rọ̀ yàrá yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kò si ẹnikan, oluwa mi, ọba; bikoṣe Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israeli, ni nsọ fun ọba Israeli gbogbo ọ̀rọ ti iwọ nsọ ninu iyẹ̀wu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kò sí ọ̀kan nínú wa, OLÚWA ọba mi,” ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “ṣùgbọ́n Èlíṣà, wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì, sọ fún ọba Ísírẹ́lì ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.