2 Kings 6:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, OLÚWA mi, kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.