2 Kings 6:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà sì gbàdúrà, “OLÚWA, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà OLÚWA la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Èlíṣà ká.