2 Kings 6:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati nwọn de Samaria ni Eliṣa wipe, Oluwa la oju awọn enia wọnyi, ki nwọn ki o lè riran. Oluwa si là oju wọn; nwọn si riran; si kiyesi i, nwọn mbẹ li ãrin Samaria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Èlíṣà wí pé, “OLÚWA, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà OLÚWA la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samáríà.