2 Kings 6:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dahùn pe, Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ, ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ̀ oluwa wọn lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Má se pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi ṣíwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.”