2 Kings 6:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliṣa jókòó ninu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn alàgbà. Ọba rán ọkunrin kan ṣáájú láti lọ pa á, ṣugbọn Eliṣa sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ apànìyàn yìí ti rán ẹnìkan láti wá pa mí, ọba fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀lé e bọ̀ lẹ́yìn. Bí iranṣẹ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà kí ó má lè wọlé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Eliṣa joko ninu ile rẹ̀, ati awọn àgbagba joko pẹlu rẹ̀; ọba si rán ọkunrin kan ṣãju rẹ̀ lọ: ṣugbọn ki iranṣẹ na ki o to dé ọdọ rẹ̀, on wi fun awọn àgbagba pe, Ẹ wò bi ọmọ apania yi ti ranṣẹ lati mu ori mi kuro? ẹ wò, nigbati iranṣẹ na ba de, ẹ tì ilẹ̀kun, ki ẹ si dì i mu ṣinṣin li ẹnu-ọ̀na: iro-ẹsẹ̀ oluwa rẹ̀ kò ha wà lẹhin rẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyí Èlíṣà jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbààgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ṣé èyin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin nítorí rẹ̀, kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀ wà lẹ́yìn rẹ?”