2 Kings 6:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dé, ó ní, “Láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni ibi yìí ti wá, kí ló dé tí n óo fi tún máa dúró de OLUWA fún ìrànlọ́wọ́?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi on ti mba wọn sọ̀rọ lọwọ, kiyesi i, iranṣẹ na sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá: on si wipe, Wò o, lati ọwọ Oluwa ni ibi yi ti wá, kili emi o ha duro dè Oluwa mọ si?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de OLÚWA sí i?”