2 Kings 7:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá lọ sí Samaria, wọ́n sì kígbe pe àwọn aṣọ́nà láti ẹnubodè pé, “A ti lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, a kò rí ẹnìkan kan níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbúròó ẹnìkan kan. Àwọn ẹṣin ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn wà bí wọ́n ṣe so wọ́n mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn àgọ́ wọn sì wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Siria ti fi wọ́n sílẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn wá, nwọn si ke si awọn onibodè ilu; nwọn si wi fun wọn pe, Awa de bùdo awọn ara Siria, si kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ, bẹ̃ni kò si ohùn enia kan, bikòṣe ẹṣin ti a so, ati kẹtẹkẹtẹ ti a so, ati agọ bi nwọn ti wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn oníbodè wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.”