2 Kings 7:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si dide li oru, o si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Emi o fi hàn nyin nisisiyi eyiti awọn ara Siria ti ṣe si wa. Nwọn mọ̀ pe, ebi npa wa; nitorina nwọn jade lọ ni bùdo lati fi ara wọn pamọ́ ni igbẹ wipe, Nigbati nwọn ba jade ni ilu, awa o mu wọn lãyè, awa o si wọ̀ inu ilu lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì dìde ní ùru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣọ fún yín ohun tí àwọn ará Ṣíríà tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sá pamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè àwa yóò yí wọ inú ìlú lọ.’ ”