2 Kings 7:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun náà dá ọba lóhùn pé, “Ṣebí àwọn eniyan náà yóo kú ni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á rán àwọn ọkunrin kan pẹlu ẹṣin marun-un tí ó kù láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si dahùn o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o mu marun ninu ẹṣin ti o kù, ninu awọn ti o kù ni ilu, kiyesi i, nwọn sa dabi gbogbo ọ̀pọlọpọ Israeli ti o kù ninu rẹ̀; kiyesi i, ani bi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia Israeli ti a run, si jẹ ki a ranṣẹ lọ iwò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Mú ọkùnrin díẹ̀ mú márùnún lára àwọn ẹsin tí wọ́n fi sílẹ̀ nínú ìlú. Ìwà wọn yóò dà bí gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì tí ó kù níbẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò dà bí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì, yìí nìkan tí a run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”